Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 29:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.”

12. Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”

13. Olúwa wí pé:“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọnwọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.Ìsìn wọn fún mini a gbé ka orí òfin tí àwọnọkùnrin kọ́ ni.

14. Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yaàwọn ènìyàn yìí lẹ́nupẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”

15. Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbunláti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùntí wọ́n sì rò pé,“Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”

16. Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé“Òun kọ́ ló ṣe mí”?Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,“kò mọ nǹkan”?

17. Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́a kò ní sọ Lẹ́bánónì di pápá ẹlẹ́tù lójúàti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí ihà?

18. Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,láti inú fìrífìrí àti òkùnkùnni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.

Ka pipe ipin Àìsáyà 29