Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 25:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ní ori òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò ti pèṣèàṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyànàpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnìtí ó gbámúṣé.

7. Ní orí òkè yìí ni yóò parunaṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀;

8. Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa gbogbo ayé yóò sì nu gbogbo omijé nù,kúrò ní ojúu gbogbo wọn;Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn an rẹ̀ kúròní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

9. Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un rẹ̀, òun sì gbà wá là.Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú un wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

10. Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìíṣùgbọ́n a ó tẹ Móábù mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀;gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.

11. Wọn yóò na ọwọ́ọ wọn jáde nínú un rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ọ rẹ̀jáde láti lúwẹ̀ẹ́.Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ọwọ́ ọ wọn.

12. Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀wọn yóò sì wà nílẹ̀Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,àní sí erùpẹ̀ lásán.

Ka pipe ipin Àìsáyà 25