Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 25:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run un mi;Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sìfi ìyìn fún orúkọọ̀ rẹnítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́o ti ṣe ohun ńlá,àwọn ohun tí o ti gbèròo rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.

2. Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,ìlú olódi ti di ààtàn,ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;a kì yóò tún un kọ́ mọ́.

3. Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóòbọ̀wọ̀ fún ọ;àwọn ìlú orílẹ̀ èdè aláìláàánúyóò bọlá fún ọ.

4. Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòsìààbò fún aláìní nínú ìpọ́njúu rẹ̀ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjìbòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.Nítorí pé èémí àwọn ìkàdàbí ìjì tí ó bì lu ògiri

5. àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní ihà.O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,gẹ́gẹ́ bí òjìji kùrukùru ṣe ń dín ooru kù,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

6. Ní ori òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò ti pèṣèàṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyànàpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnìtí ó gbámúṣé.

Ka pipe ipin Àìsáyà 25