Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 19:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ní ọjọ́ náà ìlú márùn ún ní ilẹ̀ Éjíbítì yóò sọ èdè àwọn ará Kénánì, wọn yóò sì búra àtìlẹyìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.

19. Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárin gbùngbùn Éjíbítì, àti ọ̀wọ̀n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀.

20. Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Éjíbítì. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbéjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.

21. Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ará Éjíbítì àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ oníhóró, wọn yóò jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ.

22. Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn kan bá Éjíbítì jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.

23. Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Ásíríà yóò lọ sí Éjíbítì àti àwọn ará Éjíbítì lọ sí Ásíríà. Àwọn ará Éjíbítì àti ará Ásíríà yóò jọ́sìn papọ̀.

24. Ní ọjọ́ náà Ísírẹ́lì yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Éjíbítì àti Áṣíríà, àní oríṣun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé.

25. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Éjíbítì ènìyàn mi, Áṣíríà iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Ísírẹ́lì ìní mi.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 19