Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 19:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìṣàn ọkàn yóò ṣe.

11. Àwọn oníṣẹ́ Ṣóánì ti di aláìgbọ́n,àwọn ọlọgbọ́n olùdámọ̀ràn Fáráòń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.Báwo ló ṣe lè sọ fún Fáráò pé,“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba ijọ́un.”

12. Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?Jẹ́ kí wọn fi hàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mímọ̀ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogunti pinnu lórí Éjíbítì.

13. Àwọn oníṣẹ́ Ṣóárì ti di aláìgbọ́n,a ti tan àwọn adarí Méḿfísì jẹ;àwọn òkúta igunlé tí í ṣe ti ènìyàn rẹti ṣi Éjíbítì lọ́nà.

14. Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú un wọn;wọ́n mú Éjíbítì ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nínúohun gbogbo tí ó ń ṣe,gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n nínú èébì i rẹ̀.

15. Kò sí ohun tí Éjíbítì le ṣe—orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.

16. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn.

17. Ilẹ̀ Júdà yóò da wárìwàrì jó àwọn ará Éjíbítì; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Júdà létíi wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbérò láti ṣe sí wọn.

18. Ní ọjọ́ náà ìlú márùn ún ní ilẹ̀ Éjíbítì yóò sọ èdè àwọn ará Kénánì, wọn yóò sì búra àtìlẹyìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.

19. Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárin gbùngbùn Éjíbítì, àti ọ̀wọ̀n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀.

20. Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Éjíbítì. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbéjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 19