Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 18:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ègbé ni fún ìwọ ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́,ní àwọn ipadò Kúṣì,

2. tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí òkunlórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi kóríko ṣe.Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀-ara wọn jọ̀lọ̀,sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,orílẹ̀ èdè aláfojúdi alájèjì èdè,tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

3. Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,nígbà tí a bá gbé àṣíá kan ṣókè lórí òkè,ẹ ó rí i,nígbà tí a bá fun fèrè kanẹ ó gbọ́ ọ.

4. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ ẹ́, n ó sì máa wo òréréláti ibùgbé e mi wá,gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànsán òòrùn,gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárin gbùngbùn ìkóórè.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 18