Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 11:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,Ọmọdé yóò ki ọwọ́ọ rẹ̀ bọ ìtẹ́ẹ paramọ́lẹ̀.

9. Wọn kò ní ṣeni lọ́ṣẹ́ tàbí panirunní gbogbo òkè mímọ́ mi,nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwagẹ́gẹ́ bí omi ti í bo òkun.

10. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jéésè yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àṣíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀ èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.

11. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Ásíríà wá, láti ìsàlẹ̀ Éjíbítì àti Òke Éjíbítì, láti Kúṣì, láti Élámù láti Babilóníà, láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù inú òkun.

12. Òun yóò gbé àṣíá sókè fún àwọn orílẹ̀ èdè,yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì jọ,yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí a ti fọ́n káàkiri jọ,láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.

13. Owú jíjẹ Éfáímù yóò pòórá,àwọn ọ̀tá Júdà ni a ó ké kúrò,Éfáímù kò ní jowúu Júdà,tàbí Júdà kó dojú kọ Éfáímù.

Ka pipe ipin Àìsáyà 11