Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Ásíríà wá, láti ìsàlẹ̀ Éjíbítì àti Òke Éjíbítì, láti Kúṣì, láti Élámù láti Babilóníà, láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù inú òkun.