Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 10:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùntàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa.Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

5. “Ègbé ni fún àwọn ará Ásíríà, ọ̀gọ ìbínú mi,ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

6. Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́runMo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínúláti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógunláti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

7. Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;èrò rẹ̀ ni láti parun,láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè.

8. ‘Kì í haá ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.

9. ‘Kì í ha á ṣe pé Kálínò dàbí i Káṣẹ́míṣì?Hámátì kò ha dàbí i Ápádì,àti Ṣamáríà bí i Dámásíkù?

10. Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,Ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jérúsálẹ́mù àti Ṣamáríà lọ.

11. Èmi kì yóò a bá Jérúsálẹ́mù wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Ṣamáría àti àwọn ère rẹ̀?

12. Nígbà tí Olúwa bá parí iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Ṣíhónì àti Jérúsálẹ́mù, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ Ásíríà nítoríi gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojúu rẹ̀.

13. Nítorí ó sọ pé:“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ọ̀ mi ni mo fi ṣe èyíàti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀ èdè kúrò,Mo sì ti kó ìṣúra wọn.Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.

14. Bí ènìyàn tií tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ọ̀ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè.Bí ènìyàn tii kó ẹyin tí a kọ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀ èdèkò sí èyí tí ó fapálupá,tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

15. Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,tàbí kí ayùn fọnnu sí ẹni tí ó ń lò ó?Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

16. Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,yóò rán àrùn ìrẹ̀dànù sóríàwọn akíkanjú jagunjagun,lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọgẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

Ka pipe ipin Àìsáyà 10