Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 1:3-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Màlúù mọ olówó rẹ̀,kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kò mọ̀,òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”

4. Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,Ìran àwọn aṣebi,àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀wọn ti gan Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì,wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.

5. Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,gbogbo ọkan yín sì ti pòrúúru.

6. Láti àtẹ́lẹṣẹ̀ yín dé àtàrí yínkò sí àlàáfíà rárá,àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapaàti ojú egbò,tí a kò nùnù tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.

7. Orílẹ̀-èdè yín dahoro,a dáná sun àwọn ìlú yín,oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ runlójú ara yín náà,ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tíàwọn àjèjì borí rẹ̀.

8. Ọmọbìnrin Ṣíónì ni a fi sílẹ̀gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,gẹ́gẹ́ bí àbá nínú oko ẹ̀gúsí,àti bí ìlú tí a dótì.

9. Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogunbá sẹ́ díẹ̀ kù fún wà,a ò bá ti rí bí Sódómù,a ò bá sì ti dàbí Gòmórà.

10. Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,ẹ̀yin aláṣẹ Sódómù,tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà!

11. “Ọpọ̀lọpọ̀ ẹbọ yínkín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí.“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísunti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,Èmi kò ní inú dídùnnínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntànàti ti orúkọ.

12. Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,ta ni ó bèèrè èyí lọ́wọ́ ọ yín,Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?

Ka pipe ipin Àìsáyà 1