Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìran sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù èyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí ní àsìkò ìjọba Hùṣáyà, Jótamù, Áhásì àti Heṣekáyà àwọn ọba Júdà.

2. Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!Nítorí Olúwa ti sọrọ̀:“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

3. Màlúù mọ olówó rẹ̀,kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kò mọ̀,òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”

4. Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,Ìran àwọn aṣebi,àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀wọn ti gan Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì,wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.

5. Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,gbogbo ọkan yín sì ti pòrúúru.

6. Láti àtẹ́lẹṣẹ̀ yín dé àtàrí yínkò sí àlàáfíà rárá,àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapaàti ojú egbò,tí a kò nùnù tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.

7. Orílẹ̀-èdè yín dahoro,a dáná sun àwọn ìlú yín,oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ runlójú ara yín náà,ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tíàwọn àjèjì borí rẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 1