Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 24:5-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọ́n sì kọjá odò Jọ́dánì, wọ́n sì pàgọ́ ní Áróérì, ní ìhà apá ọtún ìlú tí ó wà láàrin àfonífojì Gádì, àti sí ìhà Jásérì.

6. Wọ́n sì wá sí Gílíádì, àti sí ilé Tátímhódíṣì; wọ́n sì wá sí Dan-Jaanì àti yíkákiri sí Sídónì,

7. Wọ́n sì wá sí ìlú olodi Tírè, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hífì, àti ti àwọn ará Kénánì: wọ́n sì jáde lọ síhà gúsù ti Júdà, àní sí Bééríṣébà.

8. Wọ́n sì la gbogbo ilẹ̀ náà já, wọ́n sì wá sí Jérúsálẹ́mù ní òpin oṣù kẹsàn-án àti ogúnjọ́.

9. Jóábù sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́: ó sì jẹ́ òjì ọ̀kẹ́ ọkùnrin alágbára ní Ísírẹ́lì, àwọn onídà: àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọkẹ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ènìyàn.

10. Àyà Dáfídì sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dáfídì sì wí fún Olúwa pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe: ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, Olúwa, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jìn ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!”

11. Dáfídì sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gádì wòlíì wá, aríran Dáfídì wí pé:

12. “Lọ kí o sì wí fún Dáfídì pé, ‘Bàyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ”

13. Gádì sì tọ Dáfídì wá, ó sì bi í léèrè pé, “Kí ìyàn ọdún méje ó tọ̀ ọ́ wá ní ilẹ̀ rẹ bí? Tàbí kí ìwọ máa sá ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀ta rẹ, nígbà tí wọn ó máa lé ọ? Tàbí kí àrun ìparun ijọ́ mẹ́ta ó wá sí ilẹ̀ rẹ? Ròó nísinsin yìí, kí o sì mọ èsì tí èmi ó mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”

14. Dáfídì sì wí fún Gádì pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí a fi ara wa lé Olúwa lọ́wọ́; nítorí pé àánú rẹ̀ pọ̀; kí ó má sì ṣe fi mí lé ènìyàn lọ́wọ́.”

15. Olúwa sì rán àrùn ìparun sí Ísírẹ́lì láti òwúrọ̀ títí dé àkókò tí a dá: ẹgbàá márùndínlógójì ènìyàn sì kú nínú àwọn ènìyàn náà láti Dánì títí fi dé Bééríṣébà.

16. Nígbà tí ańgẹ́lì náà sì nawọ́ rẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù láti pa á run, Olúwa sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì sọ fún ańgẹ́li tí ń pá àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó tó, dá ọwọ́ rẹ dúró wàyìí!” Ańgẹ́lì Olúwa náà sì wà níbi ìpakà Áráúnà ará Jèbúsì.

17. Dáfídì sì wí fún Olúwa nígbà tí ó rí ańgẹ́li tí ń kọlu àwọn ènìyàn pé, “Wò ó, èmi ti ṣẹ̀, èmi sì ti hùwà búburú ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn wọ̀nyí, kín ni wọ́n ha ṣe? Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, kí ó wà lára mi àti ìdílé baba mi.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 24