Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 20:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọkùnrin Bélíálì kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣébà ọmọ Bíkírì ará Bẹ́ńjámínì; ó sì fún ìpè ó sì wí pé,“Àwa kò ní ipa nínú Dáfídì,bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jésè!Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Ísírẹ́lì!”

2. Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì lọ kúrò lẹ́yìn Dáfídì, wọ́n sì ń tọ́ Ṣébà ọmọ Bíkírì lẹ́yìn: ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Júdà sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jódánì wá títí ó fi dé Jérúsálẹ́mù.

3. Dáfídì sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ile, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì ṣé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó.

4. Ọba sì wí fún Ámásà pé, “Pè àwọn ọkùnrin Júdà fún mi níwọn ijọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìnyìí.”

5. Ámásà sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Júdà; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un.

6. Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, “Nísinsinyìí Ṣébè ọmọ Bíkírì yóò ṣe wá ní ibi ju ti Ábúsálómù lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má baà rí ìlú olódì wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.”

7. Àwọn ọmọkùnrin Jóábù sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kérétì, àti àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára: wọ́n sì ti Jérúsálẹ́mù jáde lọ, láti lépa Ṣábà ọmọ Bíkírì.

8. Nígbà tí wọ́n dé ibi òkútà ńlá tí ó wà ní Gíbíónì, Ámásà sì ṣáájú wọn, Jóábù sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.

9. Jóábù sì bi Ámásà léèrè pé, “Ara rẹ kò le bí, ìwọ arákùnrin mi?” Jóábù sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Ámásà ní irungbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

10. Ṣùgbọ́n Ámásà kò sì kíyèsí idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Jóábù: bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́: ó sì kú. Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì.

11. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Jóábù sì dúró tì í, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Jóábù? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dáfídì, kí ó máa tọ Jóábù lẹ́yìn.”

12. Ámásà sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì ríi pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú ìgbẹ́, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró.

13. Nígbà tí ó sì gbé e kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Jóábù lẹ́yìn láti lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì.

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 20