Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Sámúẹ́lì 17:20-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Áhímásì àti Jónátanì gbé wà?”Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jérúsálẹ́mù.

21. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dáfídì ọba. Wọ́n sọ fún Dáfídì pé, “Dìde kí o sì gòkè odò kánkán: nítorí pé bayìí ni Áhítófélì gbìmọ̀ sí ọ.”

22. Dáfídì sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jódánì: kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jódánì.

23. Nígbà tí Áhítófélì sì ríi pé wọn kò fi ìmọ̀ tirẹ̀ ṣe, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni gàárí, ó sì dìde, ó lọ ilé rẹ̀, ó sì palẹ̀ ilé rẹ̀ mọ̀, ó sì so, ó sì kú, a sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀. Ábúsálómù gbógun ti Dáfídì.

24. Dáfídì sì wá sí Mahánáímù, Ábúsálómù sì gòkè odò Jódánì, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀.

25. Ábúsálómù sì fi Ámásà ṣe olórí ogun ní ipò Jóábù: Ámásà ẹni tí í ṣe ọmọ ẹnìkan, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Itírà, ará Ísírẹ́lì, tí ó wọlé tọ Ábígáílì ọmọbìnrin Náhásì, arabìnrin Sérúíà, ìyá Jóábù.

26. Ísírẹ́lì àti Ábúsálómù sì dó ní ilẹ̀ Gílíádì.

27. Nígbà tí Dáfídì sì wá sí Mahánáímù, Ṣóbì ọmọ Nahásì ti Rábà tí àwọn ọmọ Ámónì, àti Mákírì ọmọ Ámíélì ti Lodebárì, àti Básíláì ará Gílíádì ti Rógélímù.

28. Mú àwọn àkéte, àti àwọn àwo, àti ìkòkò amọ̀, àti àlìkámà, àti ọkà, àti ìyẹ̀fun, àti àgbàdo díndín, àti ẹ̀wà, àti erèé, àti ẹ̀wà díndùn.

29. Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàsì màlúù, wá fún Dáfídì àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ: nítorí tí wọ́n wí pé, “Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní ihà.”

Ka pipe ipin 2 Sámúẹ́lì 17