Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 8:14-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà náà Hásáélì fi Èlíṣà sílẹ̀ ó sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí Bẹnihádádi bèèrè, “Kí ni ohun tí Èlíṣà sọ fún ọ?” Hásáélì dá a lóhùn, “Ó sọ fún mi wí pé ìwọ yóò sàn nítòótọ́.”

15. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì ó mú aṣọ tí ó nípọn, ó sì kì í bọ inú omi ó sì tẹ̀ẹ́ sí ojú ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Nígbá náà Hásáélì sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

16. Ní ọdún karùn-ún ti Jórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jéhóṣáfátì jẹ́ ọba Júdà, Jéhórámù ọmọ Jéhóṣáfátì bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Júdà.

17. Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ.

18. Ó sì rìn ní ọ̀nà ọba Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti lọ, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Áhábù ó sì ṣe ohun búburú níwájú Olúwa.

19. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì. Olúwa kò fẹ́ pa Júdà run, ó ti ṣèlérí láti ṣètọ́jú ìmọ́lẹ́ fún Dáfídì àti àwọn ilé rẹ̀ títí láéláé.

20. Ní àsìkò Jéhórámù, Édómù ṣọ̀tẹ̀ lórí Júdà, ó sì jẹ́ ọba fúnrararẹ̀.

21. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhórámù lọ sí Ṣáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Édómù sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀ síbẹ̀, sá padà lọlé.

22. Títí ó fi di òní, Édómù wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Júdà, Líbinà ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà.

23. Gẹ́gẹ́ bí fún iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Jórámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà?

24. Jórámù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú Dáfídì, Áhásáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

25. Ní ọdún méjìlá Jórámù ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Áhásáyà ọmọkùnrin Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.

26. Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní ọdún kan ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Átalíàh, ọmọbìnrin Ómírìe ọba Ísírẹ́lì.

27. Nígbà tí ó rin ọ̀nà ilé Áhábù ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó tan nípa ìgbéyàwó sí ìdílé Áhábù.

Ka pipe ipin 2 Ọba 8