Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 7:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èlíṣà wí pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, a ó ta òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná kan ní ṣékélì kan àti méjì òṣùwọ̀n ọkà fún ṣékélì kan ní ẹnu bodè Samáríà.”

2. Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ẹ wòó, tí Olúwa bá tilẹ̀ sí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀?”“Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ,” Èlíṣà dáhùn, “ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkankan lára rẹ̀!”

3. Nísinsìn yìí àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé ibodè ìlú. Wọ́n wí fún olúkúlùkù pé, “kí ni ó dé tí àwa yóò fi jókòó síbí títí àwa yóò fi kú?

4. Tí àwa bá wí pé, ‘Àwa lọ sí ìlú, ìyàn wà níbẹ̀,’ àwa yóò sì kú. Tí àwa bá dúró níbí, a máa kú, ǹjẹ́ Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibùdó ti àwọn ará Síríà kí àwa kí ó sì tẹríba. Bí wọ́n bá dá wa sí, àwa yóò yè, tí wọ́n bá sì pa wá, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò kú.”

5. Ní àfẹ̀mójúmọ́ wọ́n dìde wọ́n sì lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà. Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó náà, kò sí ọkùnrin kan níbẹ̀,

6. Nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Síríà gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Ísírẹ́lì ti bẹ ogun àwọn Hítì àti àwọn ọba Ígíbítì láti dojúkọ mú u wá!”

7. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn.

8. Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú.

9. Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Àwa kò ṣe ohun rere. Oni yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa si paamọ́ ara wa. Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjayà yóò jẹ́ ti wa. Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba.”

Ka pipe ipin 2 Ọba 7