Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 6:22-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. “Má se pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi ṣíwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.”

23. Bẹ́ẹ̀ ni ó pèṣè àṣè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Árámù dáwọ́ ìgbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì dúró.

24. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Bẹni-Hádádì ọba Árámù kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samáríà.

25. Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú náà; wọ́n dúró tìí tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́ọ̀rùnún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn ún.

26. Gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sunkún sí I pé, “Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa ọba mi!”

27. Ọba sì dá a lóhùn pé, “Tí Olúwa kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, níbo ni èmi ti lè rí ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀? Láti inú ilé ìpakà? Láti inú ibi ìfúntí?”

28. Nígbà náà ó béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?”Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’

29. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.”

30. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀.

31. Ó sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Èlíṣà ọmọ Sáfátì kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní!”

32. Nísinsìnyí Èlíṣà jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbààgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Èlíṣà sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ṣé èyin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dì í mú ṣinṣin nítorí rẹ̀, kì í ṣe ìró ẹsẹ̀ ọ̀gá rẹ̀ wà lẹ́yìn rẹ?”

33. Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a. Ọba náà sì wí pé, “Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni. Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de Olúwa sí i?”

Ka pipe ipin 2 Ọba 6