Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 25:15-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Olórí ìjọ̀ba ẹ̀sọ́ mu ìfọnná, àti ọpọ́n, èyí tí wọ́n fi wúrà àti Sílifà ṣe lọ.

16. Bàbà méjì láti ara ọ̀wọ̀n òkú àti ìjòkòó, tí Ṣólómónì ti ṣe fún ilé Olúwa, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ.

17. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ ẹsẹ̀ méjìlélógún Olórí Bàbà lórí ọkẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀wọ̀n ọ̀gá ni ìwọ̀n mẹ́rin àti ààbò wọn sì ṣe lọ́sọ́ọ̀ pẹ̀lú iṣe àwọ̀n àti àwọ pòmégránátè tí ó wà lórí ọ̀nà orí gbogbo rẹ̀ yíká, ọ̀wọ̀n mìíràn, pẹ̀lú iṣẹ́ híhun, wọ́n sì kéré.

18. Olórí àwọn ọ̀sọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n Ṣéráíáyà olórí àwọn àlùfáà, Ṣéfáníà àlùfáà ẹni tí ó kù nínú oyè gíga àti àwọn olùṣọ́nà mẹ́ta.

19. Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìjòyè tí ó fi sí ipò olórí àwọn ológun ọkùnrin àti àwọn agbà oní ní ìmọ̀ràn ọba. Ó sì tún mú akọ̀wé tí ó jẹ́ ìjòyè tí ń to àwọn ènìyàn ilé náà àti mẹ́fà nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú.

20. Nebukadínésárì olórí àwọn ẹ̀sọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà.

21. Níbẹ̀ ní Ríbílà, ní ilẹ̀ Hámátì, ọba sì kọlù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni Júdà lọ sí oko ẹrú, kúrò láti ilé rẹ̀.

22. Nebukadínésárì ọba Bábílónì ó mú Gédalíàh ọmọ Áhíkámù ọmọ ṣáfánì, láti jọba lórí àwọn ènìyàn tí ó ti fa kalẹ̀ lẹ́yìn ní Júdà.

23. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gédálíàh gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gédálíàh ni Mísípà. Ísímáélì ọmọ Nétaníàh, Jóhánánì ọmọ Káréà, Séráíáyà ọmọ Tánhúmétì ará Nétófátì, Jásáníáyà ọmọ ara Mákà, àti àwọn ọkùnrin wọn.

24. Gédálíà sì búrà láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará káidéà,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Bábílónì, yóò sì dára fún un yín.”

25. Ní oṣù kèje, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, Ísmáélì ọmọ Nétaníáyà, ọmọ Èlísámà, ẹni tí ó jẹ́ ti ẹ̀jẹ̀ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ó sì kọlù Gédálíáyà àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹwàá ará Júdà àti àwọn ará káídéà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Míspà.

26. Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sá lọ si Éjíbítì nítorí ẹ̀rù àwọn ará Bábílónì.

Ka pipe ipin 2 Ọba 25