Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 23:35-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Jéhóíákímù sì san fún Fáráò Nékónì fàdákà àti wúrà tí ó béèrè. Lati ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín.

36. Jéhóíákímù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kànlá orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣébídà ọmọbìnrin Pédáíáyà ó wá láti Rúmà.

37. Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.

Ka pipe ipin 2 Ọba 23