Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 2:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Èlíjà wà?” Ó bèèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, ó sì rékọjá.

15. Àwọn ọmọ wòlíì láti Jẹ́ríkò, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Èlíjà simi lé Èlíṣà.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú rẹ̀.

16. “Wò ó,” wọ́n wí pé, “Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára. Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá. Bóyá ẹ̀mí Olúwa ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀.”“Rárá,” Èlíṣà dá a lóhùn pé, “Má ṣe rán wọn.”

17. Ṣùgbọ́n wọ́n forítì í títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò ríi.

18. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Èlíṣà, tí ó dúró ní Jẹ́ríkò, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”

19. Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Èlíṣà, pé “Wò ó, Olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà kò dára ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”

20. Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.

21. Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà ṣá.’ ”

22. Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà ti sọ.

Ka pipe ipin 2 Ọba 2