Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 19:4-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó lè jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yóò gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ olùdarí pápá, ẹni tí ọ̀gá rẹ̀, ọba Ásíríà, ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè sẹ̀sín, yóò sì báa wí fún ọ̀rọ̀ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún ìyókù àwọn tí ó wà láàyè.”

5. Nígbà tí ìránṣẹ́ ọba Héṣékáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Àìṣáyà,

6. Àìṣáyà wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Áṣíríà ti sọ̀rọ̀ òdì sí mi.

7. Gbọ́! Èmi yóò rán ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ nígbà tí ó bá sì gbọ́ ariwo, yóò sì padà sí ìlú rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi yóò sì gbé gée lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”

8. Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Áṣíríà ti kúrò lákìsì ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Líbíńà jà.

9. Nísinsìn yìí Ṣenakéríbù sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tíránákà, ọba Etiópíà ti Éjíbítì wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán onísẹ́ sí Héṣékíáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé:

10. “Sọ fún Héṣékíáyà ọba Júdà pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí o gbékalẹ̀ kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jérúsálẹ́mù a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Ásíríà.’

11. Lọ́ọ̀tọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Ásíríà tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátapáta. Ìwọ yóò sì gbàlà?

12. Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn babańlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gósánì, Háránì Réṣéfù àti gbogbo ènìyàn Édẹ́nì tí wọ́n wà ní Télásárì?

13. Níbo ni ọba Hámátì wa, ọba Árípádì, ọba ìlú Séfárífáímù, ti Hénà, tàbí ti Ífà gbé wà?”

14. Heṣekíàyà gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ ṣíwájú Olúwa.

15. Heṣekáyà gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ń gbé ní àárin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.

16. Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú ù rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Ṣenakérúbù tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.

17. “Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Ásíríà ti pa orílẹ̀ èdè wọ̀nyìí run àti ilẹ̀ wọn.

18. Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe Olúwa. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn.

19. Nísinsìn yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkanṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa.”

20. Nígbà náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán oníṣẹ́ sí Heṣekíàyà pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Ṣenakérúbù ọba Ásíríà.

Ka pipe ipin 2 Ọba 19