Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 18:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ní ọdún kẹrin ọba Heṣekáyà, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hóséà ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì. Ṣálímánésérì ọba Áṣíríà yàn lára Ṣamáríà ó sì tẹ̀dó tì í.

10. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Ásíríà gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Ṣamáríà ní ọdún kẹfà Heṣekáyà tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì.

11. Ọba Áṣíríà lé Ísírẹ́lì kúrò ní Áṣíríà, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hálà, ní Gósánì létí odò Hábórì àti ní ìlú àwọn ará Médíà.

12. Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa ti pa láṣẹ. Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde.

13. Ní ọdún kẹrìnlá tí Heṣekáyà jọba, Ṣenakérúbù ọba Ásíríà kọlu gbogbo ìlú olódi ti Júdà ó sì pa wọ́n run.

14. Bẹ́ẹ̀ ni Heṣekáyà ọba Júdà rán oníṣẹ́ yìí sí ọba Áṣíríà ní Lákísì, “Mo ti mú ìṣe ohun tí kò dára kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba bu ọ̀ọ́dúnrún talẹ́ntì fàdákà àti ọgbọ̀n talẹ́ntì wúrà.

15. Heṣekáyà fún un ní gbogbo fàdákà tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa àti nínú ilé ìṣúra ọba.

16. Ní àkókò yìí Heṣekáyà ọba Júdà ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, kúrò àti ti òpó tí Heṣekáyà ọba Júdà ti gbéró ó sì fi fún ọba Ásíríà.

Ka pipe ipin 2 Ọba 18