Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 14:12-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. A kó ipa ọ̀nà Júdà nípasẹ̀ Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀.

13. Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Ámásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóásì, ọmọ Áhásáyà ní Bẹti-Ṣéméṣì. Nígbà náà, Jéhóásì lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì lọ wó odi Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Éfúráímù sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà (600).

14. Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn ìdógò, ó sì dá wọn padà sí Ṣamáríà.

15. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jéhóásì, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

16. Jéhóásì sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì. Jéróbóámù ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

17. Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn ikú Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì ọba Ísírẹ́lì.

18. Fún ti ìyókù iṣẹ́ rẹ̀ nígbà ìjọba Ámásáyà, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Júdà?

19. Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákísì, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lákísì, wọ́n sì pa á síbẹ̀.

20. Wọ́n gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin, a sì sin ín sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, ní ìlú ńlá ti Dáfídì.

21. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn Júdà mú Ásáríyà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Wọ́n sì ṣe é ní ọba ní ìrọ́pò baba rẹ̀ Ámásáyà.

22. Òun ni ẹni tí ó tún Élátì kọ́, ó sì dá a padà sí Júdà lẹ́yìn tí Ámásáyà ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.

23. Ní ọdún kẹẹ̀dógún tí Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà, Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Ṣamáríà, ó sì jọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún.

24. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì. Èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.

25. Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Ísírẹ́lì padà láti Lebo-Hámátì sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jónà ọmọ Ámítaì, wòlíì láti Gátì Héférì.

26. Olúwa ti rí bí olúkúlùkù yálà ẹrú tàbí òmìnira, ti ń jìyà gidigidi; kò sì sí ẹnìkan tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ka pipe ipin 2 Ọba 14