Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Ámásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóásì, ọmọ Áhásáyà ní Bẹti-Ṣéméṣì. Nígbà náà, Jéhóásì lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì lọ wó odi Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Éfúráímù sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà (600).