Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 14:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kejì tí Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Ámásáyà ọmọ Jóásì ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.

2. Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jéhóádínì; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

3. Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dáfídì baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ́lé àpẹrẹ baba a rẹ̀ Jóásì.

4. Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.

5. Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọin-gbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba.

6. Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mósè níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé: “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

7. Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ará Édómù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ iyọ̀, ó sì fi agbára mú Ṣélà nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jókítélì, orúkọ tí ó ní títí di òní.

8. Nígbà náà, Ámásáyà rán àwọn ìránṣẹ́ sí Jóásì ọmọ Jéhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìpèlẹ́jọ́ “Wá, í bá mi lójúkorojú.”

9. Ṣùgbọ́n Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fèsì sí Ámásáyà ọba Júdà: “Òṣùṣù kan ní Lébánónì rán iṣẹ́ sí Kédárì ní Lébánónì, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó.’ Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tinú ìgbẹ́ ní Lébánónì wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀.

10. Ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsìn yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lú?”

Ka pipe ipin 2 Ọba 14