Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 10:26-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Wọ́n gbé òkúta bíbọ náà jáde láti inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì, wọ́n sì jó o.

27. Wọ́n fọ́ òkúta bíbọ ti Báálì náà túútúú, wọ́n sì ya ilé òrìṣà Báálì bolẹ̀. Àwọn ènìyàn sì ń lò ó fún ilé ìgbẹ́ títí di ọjọ́ òní.

28. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa sísin Báálì run ní Ísírẹ́lì.

29. Bí ó ti wù kí ó rí, kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá—ti sísin ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà ní Bétélì àti Dánì.

30. Olúwa sì sọ fún Jéhù pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”

31. Ṣíbẹ̀ Jéhù kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn. Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù èyí tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá.

32. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dín iye Ísírẹ́lì kù. Hásáélì fi agbára tẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo agbégbé wọn.

33. Ìlà-oòrùn ti Jọ́dánì ni gbogbo ilẹ̀ ti Gílíádì (ẹ̀kún ilẹ̀ ti Gádì, Rúbẹ́nì, àti Mánásè) láti Áróérì, tí ó wà létí Ánónì Gọ́ọ́jì láti ìhà Gílíádì sí Básánì.

34. Fún ti òmìíràn ti iṣẹ́ ìjọba Jéhù, gbogbo ohun tí ó ṣe, gbogbo àṣeyọrí rẹ̀, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

35. Jéhù sin mi pẹ̀lú baba a rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà Jéhóáhásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin 2 Ọba 10