Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 10:23-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Nígbà náà, Jéhù àti Jéhónádábù ọmọ Rékábù lọ sí inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì. Jéhù sì wí fún àwọn òjíṣẹ́ Báálì pé, “Wò ó yíká, kí o sì rí i pé kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan pẹ̀lú yín níbí—kìkì òjíṣẹ́ Báálì.”

24. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ inú ilé lọ láti lọ rú ẹbọ àti ọrẹ sísun. Nísinsìn yìí Jéhù ti rán ọgọ́rin ọkùnrin sí ìta pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọkùnrin tí mo ń gbé sí ọwọ́ yín ó sá lọ, yóò jẹ́ ẹ̀mí yín fún ẹ̀mí ì rẹ.”

25. Ní kété tí Jéhù ti parí ṣíṣe ọrẹ sísun, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ àti àwọn ìjòyè: “Wọlé lọ, kí o sì pa wọ́n; Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó sálọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà. Àwọn olùṣọ́ àti ìjòyè ju ara wọn síta, wọ́n sì wọ inú ojúbọ ti ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì.

26. Wọ́n gbé òkúta bíbọ náà jáde láti inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì, wọ́n sì jó o.

27. Wọ́n fọ́ òkúta bíbọ ti Báálì náà túútúú, wọ́n sì ya ilé òrìṣà Báálì bolẹ̀. Àwọn ènìyàn sì ń lò ó fún ilé ìgbẹ́ títí di ọjọ́ òní.

28. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa sísin Báálì run ní Ísírẹ́lì.

29. Bí ó ti wù kí ó rí, kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá—ti sísin ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà ní Bétélì àti Dánì.

30. Olúwa sì sọ fún Jéhù pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”

31. Ṣíbẹ̀ Jéhù kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn. Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù èyí tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá.

32. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dín iye Ísírẹ́lì kù. Hásáélì fi agbára tẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo agbégbé wọn.

33. Ìlà-oòrùn ti Jọ́dánì ni gbogbo ilẹ̀ ti Gílíádì (ẹ̀kún ilẹ̀ ti Gádì, Rúbẹ́nì, àti Mánásè) láti Áróérì, tí ó wà létí Ánónì Gọ́ọ́jì láti ìhà Gílíádì sí Básánì.

34. Fún ti òmìíràn ti iṣẹ́ ìjọba Jéhù, gbogbo ohun tí ó ṣe, gbogbo àṣeyọrí rẹ̀, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

Ka pipe ipin 2 Ọba 10