Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 10:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsìn yìí, Áhábù sì ní àádọ́rin ọmọkùnrin ní ìdílé rẹ̀ ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni, Jéhù kọ lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samáríà: sí àwọn oníṣẹ́ Jésérẹ́lì, sí àwọn àgbààgbà àti sí àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Áhábù. Ó wí pé,

2. “Ní kété tí lẹ́tà bá ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ ọ̀gá a rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹṣin, ìlú olódi kan pẹ̀lú ohun ìjà,

3. yan èyí tí ó dára àti èyí tí ó níye jùlọ nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ, kí o sì gbé e lé orí ilé baba a rẹ̀. Nígbà náà, kí o sì jà fún, ilé ọ̀gá à rẹ.”

4. Ṣùgbọ́n dẹ́rùbà wọ́n, wọ́n sì wí pé, “Tí ọba méjì kò bá le kojú ìjà sí i, báwo ni a ṣẹ le è ṣeé?”

5. Bẹ́ẹ̀ ni olùpínfúnni a fún, olórí ìlú ńlá, àwọn àgbààgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jéhù: “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; Ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù.”

6. Nígbà náà, Jéhù kọ lẹ́tà kejì síwọn, wí pé, “Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jésérẹ́lì ní ìwòyí ọ̀la.”Nísinsìn yìí, àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba, àádọ́rin wọn sì wà pẹ̀lú àwọn adarí ọkùnrin ní ìlú àwọn tí wọ́n ń bọ́ wọn.

7. Nígbà tí ìwé náà dé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ aládé bìnrin, wọ́n sì pa gbogbo àádọ́rin wọn. Wọ́n gbé orí i wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jéhù ní Jésérẹ́lì.

8. Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jéhù, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ aládé bìnrin náà wá.”Nígbà náà Jéhù pàṣẹ, “Kó wọn sí ẹ̀bú méjì sí àbáwọlé ìlẹ̀kùn ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.”

9. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jéhù jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí!?

10. Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Áhábù tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípaṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà.”

11. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa gbogbo ẹni tí ó kù ní ilé Áhábù, pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ tímọ́-tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.

12. Jéhù jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Ṣamáríà. Ní Bẹti-Ékédì tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn.

13. Ó pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Áhásáyà ọba Júdà, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?”Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Áhásáyà, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti mọ̀mọ́ ayaba.”

14. “Mú wọn láàyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Bẹti-Ékédì, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.

15. Lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò níbẹ̀, ó wá sórí Jéhónádábù ọmọ Rékábù tí ó wà ní ọ̀nà rẹ̀ láti lọ bá a. Jéhù kí i, ó sì wí pé, “Ṣé ìwọ wà ní ìbárẹ́ pẹ̀lú mi, bí èmi ti wa pẹ̀lú ù rẹ?”“Èmi wà,” Jéhónádábù dáhùn.“Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀,” Jéhù wí, “fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jéhù sì ràn án ọ́ lọ́wọ́ sókè sí inú kẹ̀kẹ́.

16. Jéhù wí pé, “Wá pẹ̀lú ù mi; kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Ọba 10