Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa gbogbo ẹni tí ó kù ní ilé Áhábù, pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ tímọ́-tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.