Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 34:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibíyìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’

26. Sọ fún ọba Júdà, ẹni tí ó rán yín láti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n nì tí íwọ gbọ́:

27. Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibíyìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí.

28. Nísinsinyìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibíyìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.

29. Nígbà náà ọba sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà jọ àti Jérúsálẹ́mù.

30. Wọ́n sì lọ sókè ní ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì gbogbo ènìyàn lati ẹní ńlá sí ẹní kékeré, ó sì kà á ní etí wọn gbogbo ọ̀rọ̀ ínú ìwé májẹ̀mú, tí wọ́n ti rí nínú ilé Olúwa.

31. Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa ofin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí ínú ìwé yìí.

32. Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù àti Bẹ́ńjámínì dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run Baba wọn.

33. Jósíà sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Ísírẹ́lì sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 34