Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 33:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nínú ààfin méjèèje ti ilé Olúwa, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run

6. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ nínú iná ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Bẹni-Hínómù, ó ń ṣe oṣó, àfọ̀ṣẹ, ìsàjẹ́ pẹ̀lú bíbéèrè lọ́dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀, àti ẹlẹ́mìí. O se ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

7. Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Solómónì, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé.

8. Èmi kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ilẹ̀ tí a yàn fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo palásẹ fún wọn. Nípa gbogbo àwọn òfin, àsẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín ní pasẹ̀ Mósè.”

9. Ṣùgbọn Mánásè mú kí Júdà àti àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

10. Ọlọ́run bá Mánásè sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i

11. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ ogun ọba Ásíríà láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Mánásè lẹ́lẹ́wọ̀n, ó fi ìkọ́ mú-un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú Ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú-un lọ sí Bábílónì.

12. Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojú rere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀.

13. Nígbà tí ó sì gbàdúrà síi, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jérúsálẹ́mù àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Mánásè mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.

14. Lẹ́yìn èyí, ó tún ìta ògiri ìlú ńlá Dáfídì kọ́. Ìhà ìwọ̀ oòrùn orísun Gíhónì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní jìnnà réré bí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ẹja àti yíyí orí òkè Ófélì; ó se é ní gíga díẹ̀. Ó mú àwọn alákòóso ológun wà ní ìdúró nínú gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà.

15. Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjòjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé Olúwa, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé Olúwa àti ní Jérúsálẹ́mù; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú.

16. Nígbà náà ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò. Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ ọpẹ́ lórí rẹ̀. Ó sì sọ fún Júdà láti sin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

17. Àwọn ènìyàn, bí ó ti wù kí ó rí, tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga. Ṣùgbọ́n sí Olúwa Ọlọ́run wọn nìkan.

18. Àwọn isẹ́ yòókù ti ìjọba Mánásè pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 33