Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 32:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ṣùgbọ́n ọkàn Heṣekáyà ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara síi inú rere tí a fi hàn án. Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lóri Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

26. Nígbà náà Heṣekáyà ronú pìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Heṣekáyà.

27. Heṣekáyà ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, Ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye.

28. Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí titun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àsémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran.

29. Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ iye àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Olúwa ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá.

30. Heṣekíà ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gíhónì. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dáfídì. Ó ṣe àṣeyọrí sí rere nínu gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé.

31. Ṣùgbọ́n nígbà tí ara àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Bábílónì láti bi í lérè nípa àmìn ìyanu tí ó sẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀.

32. Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Heṣekíà àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì nínú ìwé àwọn ọba Júdà àti Ìsírẹ́lì

33. Heṣekáyà sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin-ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dáfídì wà. Gbogbo Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Mánásè ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 32