Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 29:21-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Júdà. Ọba pàsẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Árónì, láti se èyí lórí pẹpẹ Olúwa.

22. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ: Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ: Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ.

23. Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn.

24. Àwọn àlùfáà wọn sì pa Òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Ísírẹ́lì, nítorí ọba ti pàsẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹṣẹ fún gbogbo Íṣírẹ́lì.

25. Ó sì mú àwọn Léfì dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kíḿbálì ohun èlò orin àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti palásẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dáfídì àti Gádì aríran ọba àti Nátanì wòlíì: Èyí ni a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀.

26. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ipè wọn.

27. Hésékíà sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dáfídì ọba Ísírẹ́lì.

28. Gbogbo ìjọ ènìyàn náà sì wólẹ̀ sìn, àwọn akọrin kọrin, àwọn afọ̀npè sì fọn ìpè: gbogbo wọ̀nyí sì wà bẹ́ẹ̀ títí ẹbọ sísun náà fi parí tán.

29. Nígbà tí wọ́n sì ṣe ìparí ẹbo rírú, ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ ara wọn ba, wọ́n sì sìn.

30. Pẹ̀lúpẹ́lú Heṣekáyà ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì, láti fi ọ̀rọ̀ Dáfídì àti ti Ásáfù aríran, kọrin ìyìn sí Olúwa: wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn.

31. Nígbà náà ni Hesekíáyà dáhùn, ó sì wí pé, nísinsin yìí, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀bùn fún Olúwa, ẹ súnmọ ìhín, kí ẹ sì mú ẹbọ àti ọrẹ ọpẹ́ wá sínú ilé Olúwa. Ìjọ ènìyàn sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá; àti olúkúlùkù tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, mú ẹbọ sísun wá.

32. Iye ẹbọ sísun, tí ìjọ ènìyàn mú wá, sì jẹ́ àádọ́rin akọ màlúù, àti ọgọ́rùnún àgbò, àti igba ọ̀dọ́-àgùntàn: gbogbo wọ̀nyí sì ni fún ẹbọ ṣíṣun sí Olúwa.

33. Àwọn ohun ìyà sí mímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta màlúù, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún àgùntàn.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 29