Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 28:12-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Éfùráímù Ásáríyà ọmọ Jehóhánánì, Béríkià ọmọ Méṣílemóti, Jehísikíà ọmọ Ṣaílúmù, àti Ámásà ọmọ Hádíà, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀.

13. “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” wọ́n wí pé, “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú Olúwa, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi pupọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Ísírẹ́lì.”

14. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógún sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn.

15. Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lu orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbékùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòǹhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọ̀n tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ, wọ́n sì padà sí Samaríà.

16. Ní àkókò ìgbà náà, ọba Áhásì ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà fún ìrànlọ́wọ́.

17. Àwọn ará Édómù sì tún padà wá láti kọlu Júdà kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ.

18. Nígbà tí àwọn ará Fílístínì sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n nì àti síhà gúsù Júdà. Wọ́n sẹ́gun wọ́n sì gba Béti-ṣémésì, Áíjálónì àti Gédérótì, àti Sókò, Tímínà, a ri Gímísò, pẹ̀lú ìletò wọn.

19. Olúwa sì rẹ Júdà sílẹ̀ nítorí Áhásì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ó sọ Júdà di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì se ìrékọjá gidigidi sí Olúwa.

20. Tílgátì-Pílésárì ọba Ásíríà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.

21. Áhásì mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Ásíríà: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.

22. Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Áhásì sì di aláìsòótọ́ sí Olúwa.

23. Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Dámásíkù, ẹni tí ó sẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn síríà ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Ísírẹ́lì.

24. Áhásì sì kó jọ gbogbo ohun èlò lati ilé Olúwa jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ilẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jérúsálẹ́mù.

25. Ní gbogbo ìlú Júdà ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn Ọlọ́run mìíràn. Kí ó sì mú Olúwa, Ọlọ́run àwọn Baba wọn bínú.

26. Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì.

27. Áhásì sì sùn pẹ̀lú àwọn Baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jérúsálẹ́mù ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn ìsà òkú àwọn ọba Ísírẹ́lì. Heṣekáyà ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 28