Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 28:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Áhásì sì jẹ́ ẹni ogún ọdún (20) nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́rìndínlógún (16). Gẹ́gẹ́ bí i Dáfídì bàbá rẹ̀ kò sì ṣe ohun rere ní ojú Olúwa.

2. Ó sì rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì ó sì ṣe ere dídá fún ìsìn Báálì

3. Ó sì sun ẹbọ ní àfonífojì Hínómù, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì

4. Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ̀n nì lóri òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

5. Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Síríà lọ́wọ́. Àwọn ará Síríà sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Dámásíkù.Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbékùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa.

6. Ní ọjọ́ kan Pékà, ọmọ Remalíà, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà àwọn ọmọ ogun ní Júdà nítorí Júdà ti kọ Olúwa Ọlọ́run bàbá wọn sílẹ̀.

7. Síkíiì àti Éfúráímù alágbára sì pa Máséíẹ̀ ọmọ ọba, Ásíríkámù ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elikánà igbákejì ọba.

8. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kó ní ìgbékùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (2,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Saáríà.

9. Ṣùgbọ́n wòlíì Olúwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ódédì wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Saáríà. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí Olúwa, Ọlọ́run Baba yín bínú sí Júdà ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run.

10. Nísinsinyìí ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Júdà àti Jerúsálémù ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò há jẹ̀bi Olúwa Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin?

11. Nísinsinyìí ẹ gbọ́ tèmi! Ẹ rán àwọn ìgbékùn tí ẹ̀yin ti mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹwọ̀n padà nítorí ìbínú kíkan Olúwa ńbẹ lórí yín.”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 28