Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Síríà lọ́wọ́. Àwọn ará Síríà sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Dámásíkù.Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbékùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa.