Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 25:18-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ṣùgbọ́n Jéhóáṣì ọba Ísírẹ́lì fèsì padà sí Ámásíà ọba Júdà pé, “Òṣùṣù kan ní Lẹ́bánónì rán isẹ́ sí òpépé (igi) ní Lẹ́bánónì, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwo. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lébánónì wá, ó sì tẹ òṣùṣù náà lábẹ́ ẹsẹ̀.

19. Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Édómù àti nísinsin yìí ìwọ ní ìrera àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí o fi n wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Júdà pẹ̀lu?”

20. Ámásíà, bí ó tì wù kí ó rí kò ní tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jéhóásì lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Édómù.

21. Bẹ́ẹ̀ ni Jóásì, ọba Ísírẹ́lì: òun àti Ámásíà ọba Júdà dojúkọ ara wọn ní Bẹti Ṣeméṣì ní Júdà.

22. Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì da Júdà rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀.

23. Jóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Áhásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóáṣì ọmọ Áhásáyà ní Bétì Ṣéméṣì. Nígbà náà Jóásì mú u wá sí Jérúsálẹ́mù. Ó sì wó ògiri Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà Éfíráímù sí igun ẹnu ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí ọgọ́rùnún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn.

24. Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ile Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi Édómù, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣura ààfin àti àwọn ìdógó, ó sì padà sí Saaríà.

25. Ámásíà ọmọ Jóáṣì ọba Júdà gbé fún ọdun mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn ikú Jehóaṣì ọmọ Jehóáháṣì ọba Ísírẹ́lì.

26. Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Ámásíà láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Júdà àti Ísírẹ́lì?

27. Láti ìgbà tí Ámásíà ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé Olúwa, wọ́n dìtẹ̀ síi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákíṣì ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lákiṣì, wọ́n sì paá síbẹ̀.

28. A gbé e padà pẹ̀lú ẹsin. A sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Júdà.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 25