Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 23:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ó sì wò, sì kíyèsì, ọba dúró ní ibùdúró rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afọ̀npè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn, Nígbà náà ni Ataláyà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, “ọ̀tẹ̀! ọ̀tẹ̀!”

14. Jéhóiádà àlùfáà mú àwọn alákóso ọrọrún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé: “Mú un jáde wá láàrin àwọn ọgbà, kí ẹ sì pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀le.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má se paá nínú ilé Olúwa.”

15. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti ẹnu-òde ẹsin ní ìpìlẹ̀ ààfin. Níbẹ̀ ni wọ́n sì ti pa á.

16. Jéhóiádà, nígbà náà dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.

17. Gbogbo Àwọn ènìyàn lọ sí ilé Báálì, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mátanì àlùfaà Báálì níwáju àwọn pẹpẹ.

18. Nígbà náà, Jéhóiádà tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Leì ẹni tí Dáfídì ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ọrẹ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mósè. Pẹ̀lú ayọ̀ Àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti pàsẹ.

19. Ó mú àwọn olùsọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohun-kóhun kó má baà wọlé.

20. Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákóso ọrọrún, Àwọn eni-ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn Ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa. Wọ́n lọ sínú Ààfin láti ẹnu òde tòkè. Wọ́n sì fi ọba jókoó lórí ìtẹ́.

21. Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì ń yọ̀. Ìlú naà sì dákẹ́ rọ́rọ́. Nítorí tí a pa Ataláyà pẹ̀lú idà.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 23