Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 22:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù mú Áhásáyà, ọmọ Jéhórámù tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Árábù sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà. Bẹ́ẹ̀ ni Áhásáyà ọmọ Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ní Jọba.

2. Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún kan. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Ataláyà, Ọmọ-ọmọbìnrin Ómírì.

3. Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Áhábù. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú.

4. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú bàbá a rẹ̀, wọ́n di olùgbani lámọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀.

5. Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Jórámì ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì láti gbógun ti Háṣáélì ọba Árámì ní Rámótì Gílíádì. Àwọn ará Árámì ṣá Jórámì lọ́gbẹ́;

6. Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jésírẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rámótì ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Háṣáélì ọba ÁrámìNígbà náà, Áhásáyà, ọmọ Jehórámì ọba Júdà lọ sí Jésírẹ́lì láti lọ rí Jórámì ọmọ Áhábù nítorí a ti ṣáa lọ́gbẹ́.

7. Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Áhásáyà sí Jórámí, Ọlọ́run mú ìṣubú Áhásáyà wá. Nígbà tí Áhásáyà dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jórámì láti lọ bá Jéhù ọmọ Nímísì, ẹni tí Olúwa ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Áhábù run.

8. Nígbà tí Jéhù ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Áhábù. Ó rí ọmọbìrin ọba ti Júdà àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Áhásì. Tí ó ń dásí Áhásáyà, ó sì pa wọ́n.

9. Ó lọ làti wá Áhásáyà, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sá pamọ́ ní Saaríà. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jéhù, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé “Ọmọkùnrin Jèhóṣáfátì ni, ẹni tí ó wá Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Áhásáyà tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 22