Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 20:24-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nígbà tí Àwọn èníyàn Júdà jáde sí ìhà ilé ìsọ́ ní ihà, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí àyè sá.

25. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóṣáfatì ati àwọn èniyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀.

26. Ní ọjọ́ kẹ̀rin, wọn kó ara jọpọ̀ ní àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún Olúwa. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì ìbùkún títí di òní.

27. Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jéhóṣáfátì, gbogbo àwọn ènìyan Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí Olúwa ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.

28. Wọ́n sì wọ Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin àti dùùrù àti ipè.

29. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Olúwa ti bá àwọn ọ̀ta Ísírẹ́lì jà.

30. Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jéhóṣáfátì sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún-un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká.

31. Báyìí ni Jéhóṣáfátì jọba lórí Júdà. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Júdà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ásúbà ọmọbìnrin Ṣílíhì.

32. Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Ásà kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó si ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa.

33. Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lù, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkan wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn.

34. Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóṣáfátì, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jéhù ọmọ Hánánì, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

35. Nígbà tí ó yá, Jehóṣáfátì ọba Júdà da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Áhásáyà, ọba Ísírẹ́lì, ẹni tí ó jẹ̀bi búburú ìwà.

36. Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan okọ̀ láti lọ sí Táríṣísì, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Ésíonì-Gébérì.

37. Élísérì ọmọ Dáfídì ti Máréṣà sọtẹ́lẹ̀ sí Jóhóṣáfátì, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Áhásáyà, Olúwa yóò pa ohun ti iwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 20