Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 1:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nísinsinyìí, Dáfídì ti gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jéárímù sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jérúsálẹ́mù.

5. Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrù, ti ṣe wà ní Gíbíónì níwájú àgọ́ Olúwa: Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì àti gbogbo àpèjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀.

6. Sólómónì gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú Olúwa ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀run ọrẹ sísun lórí rẹ̀.

7. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Sólómónì, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.”

8. Sólómónì dá Ọlọ́run lóhùn pé, “Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dáfídì baba à mi ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

9. Nísinsinyìí Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dáfídì di mímúsẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lóri àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.

10. Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ́nà, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí?”

11. Ọlọ́run wí fún Solómónì pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀ta rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí,

12. Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”

13. Nígbà náà ni Sólómónì sì ti ibi gígá Gíbíónì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti iwájú àgọ́ ìpàde. Ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 1