Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kíróníkà 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sólómónì ọmọ Dáfídì fìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí ìjọba rẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú u rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ó ga lọ́pọ̀lọpọ̀.

2. Nígbà náà, Sólómónì bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ sí àwọn alákóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀rún, sí àwọn adájọ́ àti sí gbogbo àwọn olórí Ísírẹ́lì, àwọn olórí ìdílé

3. Pẹ̀lú Sólómónì, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gíbíónì, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Móse ìránṣẹ́ Olúwa ti kọ́ ni ihà.

4. Nísinsinyìí, Dáfídì ti gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jéárímù sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jérúsálẹ́mù.

5. Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrù, ti ṣe wà ní Gíbíónì níwájú àgọ́ Olúwa: Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì àti gbogbo àpèjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀.

6. Sólómónì gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú Olúwa ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀run ọrẹ sísun lórí rẹ̀.

7. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Sólómónì, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.”

Ka pipe ipin 2 Kíróníkà 1