Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 23:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣọ́ọ̀lù sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti ká Dáfídì mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

9. Dáfídì sì mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Ábíátarì àlùfáà náà pé, “Mú éfódù náà wá níhínìnyìí!”

10. Dáfídì sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi.

11. Àwọn àgbà ìlú Kéílà yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Ṣọ́ọ̀lù yóò hà sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”

12. Dáfídì sì wí pé, “Àwọn àgbà ilú Kéílà yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Ṣọ́ọ̀lù lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.”

13. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìdé, wọ́n lọ kúrò ní Kéílà, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà; kò sì lọ sí Kéílà mọ́.”

14. Dáfídì sì ń gbé ní ihà, níbi tí ó ti sá pamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè-ńlá kan ní ihà Sífì. Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá a lójóojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.

15. Dáfídì sì ríi pé, Ṣọ́ọ̀lù ti jáde láti wá ẹ̀mi òun kiri: Dáfídì sì wà ní ihà Sífì nínú igbó kan.

16. Jónátanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì dìde, ó sì tọ Dáfídì lọ nínú igbó náà, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run.

17. Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Ṣọ́ọ̀lù baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 23