Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 23:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó sì ṣe, nígbà tí Ábíátarì ọmọ Áhímélékì fi sá tọ Dáfídì lọ ní Kéílà, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú éfódù kan lọ́wọ́ rẹ̀.

7. A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé Dáfídì wá sí Kéílà. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.”

8. Ṣọ́ọ̀lù sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti ká Dáfídì mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

9. Dáfídì sì mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Ábíátarì àlùfáà náà pé, “Mú éfódù náà wá níhínìnyìí!”

10. Dáfídì sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi.

11. Àwọn àgbà ìlú Kéílà yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Ṣọ́ọ̀lù yóò hà sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. Olúwa sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.”

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 23