Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 20:2-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Jónátanì dáhùn pé, “Kí a má rí i! Ìwọ kò ní kú! Wò ó baba mi kì í ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí tí ó kéré, láì fi lọ̀ mí. Èéṣe tí yóò fi fi èyí pamọ́ fún mi? Kò rí bẹ́ẹ̀.”

3. Ṣùgbọ́n Dáfídì tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojú rere ní ojú ù rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jónátanì kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Ṣíbẹ̀ nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láàyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrin èmi àti ikú.”

4. Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ.”

5. Dáfídì wí pé, “Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ́ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta.

6. Tí baba rẹ bá fẹ́ mi kù, sọ fún un pé, ‘Dáfídì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’

7. Tí o bá wí pé, ‘Ó dára náà,’ nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu. Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi.

8. Ṣùgbọ́n ní tirẹ ìwọ, fi ojú rere wo ìránṣẹ́ rẹ; nítorí tí ìwọ ti báa dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ níwájú Olúwa. Tí mo bá jẹ̀bi, pa mí fún ara rẹ! Èéṣe tí ìwọ yóò fi fi mí lé baba rẹ lọ́wọ́?”

9. Jónátanì wí pé, “Kí a má ríi! Ti mo bá ti gbọ́ tí baba mi ti pinnu láti pa ọ́ lára, ṣé èmi kò ní sọ fún ọ?”

10. Dáfídì sì béèrè pé, “Ta ni yóò sọ fún mi tí baba rẹ̀ bá dá ọ lóhùn ní ohùn líle?”

11. Jónátanì wí pé, “Wá, jẹ́ kí a jáde lọ sórí pápá.” Nígbà náà wọ́n sì jáde lọ.

12. Nígbà náà ni Jónátanì sọ fún Dáfídì: “Pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, èmi yóò rí i dájú pé mo gbọ́ ti ẹnu baba mi ní ìwòyí ọ̀la tàbí ní ọ̀túnla tí ó bá sì ní ojú rere ní inú dídùn sí ọ, tí èmi kò bá ránṣẹ́ sí ọ, kí èmi sì jẹ́ kí o mọ̀?

13. Ṣùgbọ́n tí baba mi kò bá ní ìfẹ́ sí pa ọ́ lára, kí Olúwa kí ó dí ìyà jẹ mí, tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ; tí n kò bá jẹ́ kí o mọ̀, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí Olúwa kí ó pẹ̀lú ù rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi.

14. Ṣùgbọ́n fi inú rere àìkùnà hàn mí. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè kí wọ́n má ba à pa mí,

15. Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí Olúwa tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀ta Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀.”

16. Nígbà náà ni Jónátanìf bá ilé Dáfídì dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dáfídì láti sírò”

17. Jónátanì mú kí Dáfídì tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní síi, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀.

18. Nígbà náà ni Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a ó ò fẹ́ ọ kù, nítorí àyè rẹ yóò ṣófo.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 20