Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 20:19-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí bi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Ésélù.

20. Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan.

21. Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún-un wí pé, ‘wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ;’ kó wọn wá síbí kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewú.

22. Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọdékùnrin náà pé, ‘wò ó, àwọn ọfà náà kọjá níwájú rẹ;’ nígbà náà, o gbọdọ̀ lọ, nítorí Olúwa ti rán ọ jáde lọ.

23. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí Olúwa jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti èmi títí láéláé.”

24. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sá pamọ́ sínú pápá. Nígbà tí àṣè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun sì dé, ọba sì jókòó láti jẹun.

25. Ó sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń ijòkòó lórí ìjòkó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jónátanì, Ábínérì sì jókòó ti Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n àyè Dáfídì sì ṣófo.

26. Ṣọ́ọ̀lù kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lótìítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.”

27. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dáfídì sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọmọ rẹ̀ Jónátanì pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jésè kò fi wá síbi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?”

28. Jónátanì sì dáhùn pé, “Dáfídì bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

29. Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nì yí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.”

30. Ìbínú Ṣọ́ọ̀lù sì ru sí Jónátanì ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jésè fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú mọ̀mọ́ rẹ tí ó bí ọ?

31. Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jésè bá wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹṣẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsìn yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọ́dọ̀ kú!”

32. Jónátanì béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?”

33. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jónátánì láti gún un pa. Nígbà náà ni Jónátanì mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dáfídì ni.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 20