Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 12:2-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nísinsìn yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí.

3. Èmi dúró níhìn yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi ti ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe ìkankan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún un yín.”

4. Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”

5. Samúẹ́lì sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”

6. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mósè àti Árónì àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Éjíbítì.

7. Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.

8. “Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù wọ Éjíbítì, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mósè àti Árónì, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Éjíbítì láti mú wọn jókòó níbí yìí.

9. “Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sísérà, olórí ogun Hásórì, àti sí ọwọ́ àwọn Fílístínì àti sí ọwọ́ ọba Móábù, tí ó bá wọn jà.

10. Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Báálì, àti Ásítarótì. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’

11. Nígbà náà ni Olúwa rán Jérúbù-Báálì, Bárákì, Jẹ́fítà àti Sámúẹ́lì, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà.

12. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Náhásì ọba àwọn Ámónì dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín.

13. Nísinsìn yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún; wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín.

14. Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára

15. ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín.

Ka pipe ipin 1 Sámúẹ́lì 12