Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 9:7-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. nígbà náà ni èmi yóò ké Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè.

8. Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’

9. Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn bàbá wọn jáde láti Éjíbítì wá, wọ́n sì ti gbá Ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ”

10. Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Sólómónì kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba.

11. Sólómónì ọba sì fi ogún ìlú ní Gálílì fún Hírámù ọba Tírè, nítorí tí Hírámù ti bá a wá igi kédárì àti igi fírì àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀.

12. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hírámù sì jáde láti Tírè lọ wo ìlú tí Sólómónì fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn.

13. Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nì wọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ kábúlù títí fi di òní yìí.

14. Hírámù sì ti fi ọgọ́fà (120) talẹ́ntì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.

15. Ìdí àwọn asìnrú ti Sólómónì ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkárarẹ̀; Mílò, odi Jérúsálẹ́mù, Hásórì, Mégídò àti Gésérì.

16. Fáráò ọba Éjíbítì sì ti kọlu Gésérì, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kénánì tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Sólómónì lọ́rẹ.

17. Sólómónì sì tún Gésérì kọ́, àti Bẹti Hórónì ìṣàlẹ̀,

18. Àti Bálátì àti Támárì ní ihà, láàrin rẹ̀,

19. Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Sólómónì ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ní Lébánónì àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.

20. Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Ámórì ará Hítì, Pérísì, Hífì àti Jébúsì, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Ísírẹ́lì,

21. ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò le parun pátapáta, àwọn ni Sólómónì bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.

Ka pipe ipin 1 Ọba 9