Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 6:4-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà.

5. Lára ògiri ilé náà ni ó bu yàrá yíká; àti tẹ́ḿpìlì àti ibi mímọ́ jùlọ ni ó sì ṣe yàrá yíká.

6. Yàrá ìsàlẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní ìbú, ti àárin sì jẹ́ ìgbọ̀wọ́ mẹ́fà ní ìbú, àti ẹ̀kẹta ìgbọ̀nwọ́ méje sì ni ìbú rẹ̀. Nítorí lóde ilé náà ni ó dín ìgbọ̀nwọ́ kọ́ọ̀kan káàkiri, kí igi àjà kí ó má ba à wọ inú ògiri ilé náà.

7. Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú-un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.

8. Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìṣàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúṣù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárin, àti láti yàrá àárin bọ́ sínú ẹ̀kẹ́ta.

9. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó Kédárì.

10. Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà. Gígùn ìkọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi Kédárì.

11. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sólómónì wá wí pé:

12. “Níti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dáfídì baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀.

13. Èmi yóò sì máa gbé àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èmi kì ó sì kọ Ísírẹ́lì ènìyàn mi.”

14. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀.

15. Ó sì fi pákó Kédárì tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó fírì tẹ́ ilẹ̀ ilé náà.

16. Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ.

17. Ní iwájú ilé náà, ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́.

18. Inú ilé náà sì jẹ́ Kédárì, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìtàkùn àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ Kédárì; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.

19. Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí májẹ̀mú Olúwa ka ibẹ̀.

20. Nínú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi Kédárì bo pẹpẹ rẹ̀.

21. Sólómónì sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó.

22. Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.

Ka pipe ipin 1 Ọba 6