Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 3:4-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọba sì lọ sí Gíbíónì láti rúbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Sólómónì sì rú ẹgbẹ̀rún ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.

5. Ní Gíbíónì Olúwa fi ara han Sólómónì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”

6. Sólómónì sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀ṣíwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́.

7. “Nísinsìnyìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ̀ bí mo ṣe lè ṣe àwọn ojúṣe mi.

8. Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrin àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mòye wọn.

9. Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrin rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”

10. Inú Olúwa sì dùn pé Sólómónì béèrè nǹkan yìí.

11. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún-un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀ta rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá,

12. èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dà bí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dà bí rẹ lẹ́yìn rẹ.

13. Ṣíwájú síi, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò bèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dà bí rẹ.

14. Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dáfídì baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”

15. Sólómónì jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.Ó sì padà sí Jérúsálẹ́mù, ó sì dúró níwájú àpótí májẹ̀mú Olúwa, ó sì rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àṣè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.

16. Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbérè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ.

17. Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀.

18. Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí ẹlòmíràn ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan.

Ka pipe ipin 1 Ọba 3